E Se Amin Adura
Apemora eni la a pe temidire
Ori wa ko ni ko adura
Ibukun ni fun wa ni ile
Ibukun ni fun wa ni oko
Ibukun ni fun wa ni irin ajo
Ibukun ni fun wa ninu gbogbo idawole wa fun ire
Ibukun ni fun wa ninu oogun oju fun itesiwaju eda
Odidere wa ko ni gbe si oko iwaje
A a ko ere oko dele
A ko ni tawo na
A ko ni toro je
A ko ni taraka ka to jeun
A ko ni lo akisa kehin aso
A ko ni fi oju sunkun ale
Ina ku o fi eeru boju
Ogede ku fi omo e ropo
Omo ayo ni Edumare a fi ropo wa
Laipe laijina
Akitiyan ati laalaa gbogbo wa
Pelu ti awon akoni wa ana
A so opo eso rere – Amin.
Dr Samuel Kayode Olamijulo
May 11, 2008